Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 81

Ninu iponju li awa o de Ijoba orun.

Meter: 7.7.8.7.D

Scripture: Ise A. 14:22

1

fOlorin ijo t’orun

L’ayo l’a wole fun O,

Ki O to de, Ijo t’aye;

Y’o ma korin bi t’orun’

ffA gbe okan wa s’oke

Ni ‘reti t’o ni ‘bukun,

Awa kigbe, awa f’iyin

F’Olorun igbala wa.

2

ff‘Gbat’ awa ninu ‘ponju

T’ a nkoja ninu ina

crOrin ife l’awa o ko

Ti o nmu wa sun mo O;

fAwa sa pe, a si yo

Ninu ojurere Re;

ffIfe t’o so wa di Tire,

Y’o se wa ni Tire lae.

3

pIwo mu awon eniyan Re;

Koja isan idanwo,

crA ki o beru wahala,

Tori O wa nitosi

mfAye, ese, at’Esu.

Kojuja si wa lasan

fL’agbara Re a o segun

A o si ko orin Mose.

4

mfAwa figbagbo r’ogo,

Ti o tun nfe fi wa si;

crA kegan aye nitori

Ere nla iwaju wa

pBi 0 ba si ka wa ye

Awa pelu Stefen t’o sun

fY’o ri O bi O ti duro

Lati pe wa lo s’orun.