Hymn 810
Ko si enikan ti o ni ife ti o tobiju Eyi lo pe enikan fi emi re lele nitori awon ore Re
Meter: 9.9.7.7.9. &Ref.
Scripture: Jn. 15:13
1
crJesu l’ore to dara julo
’Gbati ’gbi aye ba yi lu o;
Y’O wo okan to gbogbe,
Y’O si fi agbara fun;
Jesu l’ore to dara julo
CHORUS
mfJesu l’ore to dara ju, (Jesu l’ojojo)
(Jesu l’ore to dara ju) (Jesu n’bi gbogbo)
On ki yo je ko subu
Y’O gbo ’gbati o ba pe;
Jesu l’ore to dara julo.
2
mfOre pataki ni Jesu je,
O f’alafia kun okan mi,
Ni ’gbekele apa Re
Nko je beru ibikan;
Jesu l’ore to dara julo
3
mpBi ’banuje tile de ba mi
Ti igbi Jordan si nyi lu mi,
mfEmi ko gbodo beru,
Oluwa mbe nitosi;
Jesu l’ore to dara julo.,
4
f’Gbati a ba dele wa orun
Pelu awon to ti lo saju,
Ao korin l’ebute Re,
Ao si ma yin I titi;
Jesu l’ore to dara julo