Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 819

Alabukun fun li awon ti ko ri mi ti won si gbagbo.

Meter: 10.10.11.11

Scripture: Jn. 20:29

1

fAigbagbo bila! Temi l’Oluwa

On O si dide fun igbala mi;

Ki nsa ma gbadura, On O se ’ranwo,

’Gba Krist’ wa lodo mi ifoya ko si.

2

pB’ona mi ba su, On l’O sa nto mi,

Ki nsa gboran sa, On o si pese;

Bi iranlowo eda gbogbo saki,

Oro t’enu Re so, yo bori dandan.

3

mfIfe t’O fihan ko je ki nro pe

Y’O fi mi sile ninu wahala;

Iranwo ti mo si nri lojojumo,

O nki mi l’aya pe, emi o la ja.

4

pEmi o se kun ’tori iponju,

Tabi irora, O ti so tele,

Mo m’oro Re p’awon ajogun ’gbala,

Won ko le sai koja larin wahala.

5

pEda ko le so kikoro ago

T’Olugbala mu k’elese le ye;

Aye Re tile buru ju temi lo;

Jesu ha le jiya, kemi si ma sa?

6

mfNje b’ohun gbogbo ti nsise ire,

Fun awon to duro de Oluwa,

B’ oni tile koro, sa ko ni pe mo,

ff’Gba na orin’segun yio ti dun to?