Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 824

Nitori Emi li Oluwa, Emi koyipada.

Meter: 12.12.12.7. & Ref.

Scripture: Mal. 3:6

1

mfOlorun t’O mu Israel la okun ja

Ti O si gba won kuro li oko eru;

Ti O ro ’jo onje sile lati orun,

fOn ni mo ngbadura si.

CHORUS

Okan na loni, okan na loni,

(Bakan na ni Olorun ti mo ngbadura si)

B’ akoko t’O sin Israel la okun

(La okun ja)

Omo Re ni un o je, ’tori oro Re so

Pe, okan na ni Olorun Iyanu loni.

2

mfOlorun t’O gba Daniel lowo kiniun,

T’O si yo awon meta n’nu ina ’leru,

Eni ti awon irawo ngba Tire gbo,

fOn ni mo ngbadura si.

3

mfOlorun t’O f’oro Re d’afefe duro,

T’O si nso ’banuje oni d’ayo lola,

Eni ti O yi okuta ’boji kuro,

fOn ni mo ngbadura si.

4

mfOlorun t’O wo itanna igbe l’aso,

Eni t’O mu omi san n’iyangbe ile

Ti O we elese mo ninu eri re,

fOn ni mo ngbadura si.