Hymn 825
SO fun awon omo Israeli ki won ki o tesiwaju.
Meter: 11.11.11.7. & Ref.
Scripture: Eks. 14:15
1
fKristi Balogun wa niwaju ogun,
B’O ba ran wa n’ise a ko ni beru;
Bi ohun t’O fe se ko tile ye wa,
Sibe ao tele titi.
CHORUS
ffTesiwaju! l’ase Oluwa.
Te siwaju si ’le ’leri na;
Te siwaju ko orin soke,
Pelu Kristi, isegun daju.
2
fGbogbo ifeju esu ko le mi wa
Bi Kristi je asa at’apata wa;
Ao ma fi ida emi bi a ti nlo,
Ao ma tele titi.
3
fE jeki a gbe asia wa s’oke,
Ibi ko le de ibiti o ba wa,
Kristi, Balogun wa ti segun aye,
A o ma tele titi.
4
fB’ogunna tile le ko ni pe pari.
Nigbana, ao dapo pe l’awon mimo
Lati fi ayo ko orin isegun
Bi aba tele titi.