Hymn 826
Abo mi mbe l’odo Olorun ti O nse igbala olotito li aya.
Meter: 8.8.8.6.
Scripture: OD. 7:10
1
mpJesu mimo, Ore airi,
Oluranlowo alaini,
N’nu ayida aye ko mi
K’emi le ro mo O.
2
Ki nsa n’idapo mimo yi,
Gba ohun t’O fe uno kun bi?
B’okan mi b’eka ajara
Ba sa le ro mo O.
3
Okan mi t’are mu pupo
R’ibi isimi l’odo Re;
Ibukun ti de s’okan mi
N’tori t’o ro mo O.
4
mfB’aye d’ofo mo mi l’oju,
Ba gba ore at’ara lo,
diNi suru ati laibo ’hun
L’emi o ro mo O.
5
mp’Gba t’o k’emi nikan soso,
Larin idamu aye yi,
pMo gb’ohun ife jeje na
Wipe, “Sa ro mo Mi”.
6
crB’are ba fe mu igbagbo,
T’ireti ba si fe saki,
fKo si ewu fun okan na
Ti o ba ro mo O.
7
mfWon ko beru ’rumi aye
Nitori ’Wo wa nitosi;
Won ko si gbon b’iku ba de
’Tori won ro mo O.
8
Ire sa ni l’ohun gbogbo,
Ko s’eni le daya fo mi
’Gba mo fi O s’Olugbala,
Ti mo si ro mo O.