Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 828

lya igba isisiyi ko ye latifi se aka we ogo ti a ofi han wa.

Meter: 11.11.11.11 & Ref

Scripture: Rom. 8:18

1

crNigbati ‘gbi aye yi ba nyi lu o,

To si dabi enipe gbogbo re pin,

Ka ibukun re, siro won l’okokan,

Ise Oluwa yo je ’yanu fun o

CHORUS

mfKa ’bukun re, ka won l’okokan,

Ka ’bukun re, wo ’se Olorun;

Ka ’bukun re, ka won l’okokan,

Ka ’bukun re, wa ri ’se t’Olorun se.

2

mpEru aniyan ha nwo ’kan re l’orun!

Ise t’a pe o si ha soro fun O;

Ka ’bukun re, ’yemeji yo si fo lo,

mfOrin iyin ni yo si gb’enu re kan.

3

’Gbat’ o ba nwo awon oloro aye,

Ronu oro ti Jesu ti se leri;

Ka ibukun re, owo ko le ra won,

Ere re l’orun ati ’le re l’oke.

4

mpNinu gbogbo ayidayida aye,

mfMase foya, Olorun tobi julo;

fKa ’bukun re, awon angel’ yo to o

Won yo si ran o lowo titi d’opin.