Hymn 829
E mayo ninu Oluwa nigbagbogbo.
Meter: L.M.&Ref.
Scripture: Fili. 4:4
1
fEyo n’nu Oluwa, e yo,
Eyin t’okan re se dede;
Eyin t’o ti yan Oluwa,
Le ’banuje at’aro lo
CHORUS
ffE yo! E yo!
E yo n’nu Oluwa, e yo!
E yo!E yo
E yo n’nu Oluwa, e yo!
2
fE yo ’tori On l’Oluwa,
L’aye ati l’orun pelu;
Oro Re bori ohun gbogbo,
O l’agbara lati gbala.
3
cr’Gbat’ e ba nja ija rere,
Ti ota fere bori yin;
mfOgun Olorun t’e ko ri
Po ju awon ota yin lo.
4
mpB’okunkun tile yi o ka,
Pelu isudede gbogbo,
mfMase je k’okan re damu,
Sa gbekel’Oluwa d’opin.
5
fE yo n’nu Oluwa, e yo,
E korin iyin Re kikan;
Fi duru ati ohun ko
Aleluyal’ohungoro.