Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 843

Emi wa pelu yin nigbagbogbo, Titi o fi de opin aye.

Meter: 9.1.9.1. & Ref.

Scripture: Mat. 28:20

1

Orin kan wa ninu okan mi,

Jesu so jeje wipe;

mp“Mase beru, mo wa pelu re

Ninu ’gbi aye gbogbo”.

CHORUS

fJesu, Jesu, Jesu,

Ti o dun julo,

Gba gbogbo ife mi,

O si nmu mi korin lo

2

pEse ti ba ’gbe aye mi je,

Irora kun okan mi;

mfJesu ti mu gbogbo re kuro,

O tun ji mi nin’orun

3

Fun ipese ore-ofe Re

Fun isimi l’abe Re;

Fun oju rere Re ’gba gbogbo

fNi mo se nkorin kikan.

4

Bi mo tile nla omi ko ja,

Ti wahala wa lona;

Ti ona ko si ni igbadun,

On sa wa ni iwaju.

5

fNi aipe titi, y’O to mi wa

Lat’orun giga l’oke;

Un o fo ba lo si orun mimo,

Un o ma ba joba l’oke