Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 844

Awon eni irapada Oluwa yi o pada, Won o si wa Sioni ti awon ti orin.

Meter: 8.7.8.7

Scripture: Isa 51:11

1

mpNinu oru Ibanuje

L’awon egbe ero nrin;

mfWon nkorin ’reti at’ayo,

Won nlo sile Ileri.

2

mpNiwajuwa n’nu okunkun

Ni imole didan ntan;

mfAra ngba ara won lowo

Won nrin lo li aifoya

3

mfOkan ni imole orun

Ti ntan s’ara eniyan Re.

Ti nle gbogbo eru jina,

Ti ntan yi ona wa ka

4

Okan ni iro ajo wa,

Okan ni igbagbo wa,

Okan l’Eni ta gbekele,

Okan ni ireti wa

5

mfOkan l’orin t’egberun nko

Bi lati Okan kan wa.

Okan n’ija, okan l'ewu

Okan ni irin Orun

6

Okan ni inu didun wa,

L’ebute aini pe kun;

Nibiti Baba wa orun

Y’Oma joba titi lae

7

crNje ka ma nso, eyin ara

T’awa ti agbelebu,

Ejeka ru, ka si jiya

Tit’ao fl ri ’simi

8

fAjinde nla fere de na,

’Boji fere si sile;

Gbogbo okun yo tuka

Gbogbo okun yo si tan.