Hymn 846
Bi igi opoto ki yio tile tanna, sugbon emi o mayo ninu Oluwa,
Meter: 7.6.7.6.D.
Scripture: Hab. 3:17-18
1
mfGba’mole yo l’ojiji
Si Kristian ti nkorin;
Oluwa ni O ndide
Pelu ’mularada;
Gbati irora ndinku
On a tun fun okan
N’imole ti ntan sansan
Lati mu l’araya.
2
crPelu isaro didun,
A ranti ife Re;
mfIgbala nla n’nu Jesu,
Otun ni titi lae;
Eyi le ’banuje lo,
O nmu okan wa yo,
Ba ko tile mo ola.
A nireti didun.
3
crOhun to wu ko mu wa,
On y'O mu wa laja; .
Eni daso bo koko,
Yo da bo eniyan Re,
Labe awosanma Re,
Ko s’edati ki bo,
Eni mbo awon eye,
Y’O f’omo Re l’onje.
4
crB’ajara tab’opoto
Ko tile so eso,
Bi gbogbo ’ko tile ro
T’agbo eran segbe,
mfOlorun mbe bakanna;
fUn o korin iyin Re;
Bi mo ti ngbeke mi le,
Ayo mi yo ma po.