Hymn 860
OluwagbO, Oluwa dariji.
Meter: C.M
Scripture: Dan. 9:19
1
mfGb’adura wa, Oba aye
’Gbat’ a wole fun O;
fGbogbo wa nkigbe n’irele,
diA mbebe fun anu;
Tiwa l’ebi, Tire l’anu,
Ma se le wa pada;
Sugbon gbo ’gbe wa n’ite Re
Ran ebe wa lowo.
2
pEse awon baba wa po,
Tiwa ko si kese
Sugbon lati irandiran
L’o ti f’ore Re han
Nigba ewu, b’omi jija
Yi ilu wa yi ka,
IWO l’a wo, t’a si ke pe;
K’a ma ri ’ranwo Re.
3
pL’ohun kan gbogbo wa wole
L’abe ibawi Re;
Gbogbo wa njewo ese wa,
A ngb’awe fun ’le wa,
F’oju anu wo aini wa
Bi a ti nke pe O;
Fi idajo Re ba wa wi,
Da wa si l’anu re