Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 863

Iranlowo wa mbe li oruko Oluwa ti O da Orun on aye.

Meter: 6.6.6.6. & Ref.

Scripture: OD. 124:8

1

mfBaba,’Wol’ato wa

F’anu at’or’-ofe;

JOWO gbo igbe wa,

Mam’oju Re kuro!

CHORUS

crBaba, na ’wo agbara Re,

Ki o si bukun ile wa.

2

fDide, Oluwa wa,

JOWO foruko Re;

Le gbogbo ese lo

Kuro ni ile wa.

3

RO ojo ’bukun Re

Siwa lopolopo;

K’a le ma gbe O ga,

K’a ma yin O titi.

4

Fi ogbon Re orun

F’awon olori wa;

Se won ni iran se Re

Ki won fe ododo.

5

mfRu ijo Re soke

Pelu ina ife;

Tun dapo si okan,

F’oto at’iye fun.

6

crFi ore-ofe Re

F’awon alufa Re;

Se won l’ojise Re

Ninu iwa-mimo.

7

crJe k’a fe ile Re,

K’a ya ’jo Re soto,

K’a mu eje wa wa

Lati josin fun O.

8

mfF’alafia fun wa;

Le ota wa jinna,

K’a ma f’afojudi

Dese s’ola-nla Re.

9

B’a ti l’agidi to,

Sibe Tire ni wa

Ko s’Olorun miran

Ti ao sin lehin re.