Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 881

Awon eni irapada Oluwa nwon o ri ayo ati inu didun gba.

Meter: 10.10.10.8. & Ref.

Scripture: Isa. 35:10

1

mfBi iwo nfe ri idariji gba,

Alafia ti nle ‘banuje lo;

Woke sodo Jesu t’o ku fun o

Lati ra igbala kikun

CHORUS

crWa si abe agbelebu Re,

ka isura aye yi sofo

diWe nin’ eje t’o nsan lat’ oke

mfGba igbala re ni kikun

2

mfBi o nfe ki o joba l’okan re

We ninu isun si gba iwosan

diWa we ninu eje Odagutan

Gba igbala re ni kikun

3

mfBi o nfe ni igboya lati ja

Ma rin n’nu mole at’iwa mimo;

Lati ma sin ni omnira okan,

Gba igbala re ni kikun

4

mfRo m’agbelebu fun iwa-mimo

Ka oro aye yi s’ohun asan;

diWole lese Re, yio we o mo,

Gba igbala re ni kikun.