Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 882

Bi iwo ba gbagbo, iwo o ri ogo Olorun.

Meter: 8.7.8.7.D.

Scripture: Jn. 11:40

1

B’o ti dun lati gba Jesu

diGbo gegebi oro Re;

K’a simi lor’ileri Re,

mfSa gbagbo l’Oluwa wi

CHORUS

fJesu, Jesu, emi gbagbo,

Mo gbekele n’gba gbogbo,

Jesu, Jesu, Alabukun

Ki nle gbekele O si.

2

mfB’o ti dun lati gba Jesu,

K’a gb’eje ’wenumo Re

Igbagbo ni ki a fi bo

Sin ’eje wenumo na.

3

mfB’o ti dun lati gba Jesu,

Ki nk’ara ese sile,

Ki ngb’ayo, iye, isimi

Lati odo Jesu mi.

4

fMo yo mo gbeke mi le O,

Jesu mi, Alabukun;

Mo mo pe O wa pelu mi,

Ntoju mi titi dopin.