Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 888

Emi ni Oluso agutan rere.

Meter: 8.7.8.7.

Scripture: Jn. 10:11

1

crA le ri Olus’agutan

To feran wa bi Jesu,

Olugbala wa ti O nfe

Ka ma pejo l’ese Re

2

mfEse ti eyin fi nfonka

B’agbo-eran t’eru mba

mpEyin ope, e se nsako

Kuro labe ife Re.

3

mfAnu Olorun ti po to!

O po bi omi okun;

Ododo Re kun fun ore

To po ju omiran lo.

4

Ko si ibi ti a nkedun

F’araye ju t’orun lo;

crNibe li a nfoju anu

Wo gbogb’ asise eda.

5

mfIdariji mbe f’elese

Or’-ofe mbe f’eni re;

Anu mbe lod’ Olugbala;

Iwosan mbe n’n’eje Re

6

fIdande mbe lopolopo

N’nu eje ta ta sile;

Ayo mbe fun gbogbo aye

N’nu iya Olori wa.

7

N’tor’ ife Olorun gboro

Ju oye eniyan lo;

Ife Baba, Eni Aiku,

Je ife’yanu pupo.

8

Bi ife tiwa l’ailetan,

diA ba gbe okan wa le;

Aye wa iba kun fayo

Ninu ife Oluwa.