Hymn 89
Olorun yi, Olorun wa ni lae ati laelae.
Meter: 6.7.6.7.6.6.6.6.
Scripture: OD. 48:14.
1
fA f’ope f’Olorun,
L’okan ati l’ohun wa.
Eni s’ohun ’yanu,
N’nu eni t’araye nyo;
mf’Gbat’a wa L’om’owo
On na l’ontoju wa
O si nf’ ebun ife
Se 'toju wa sibe.
2
mfQba Onib’ore
Ma fi wa sile laelae,
Ayo ti ko l’opin
On ’bukun y’o je ti wa
Pa wa mo n’nu ore
To wa, gb’a ba damu;
Yo wa ninu ibi
L’aye ati l’orun.
3
unK’a fiyin on ope,
ffI’Olorun, Baba, Omo,
Ati Emi mimo;
Ti Oga julo lorun,
Olorun kan laelae,