Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 892

Ki oju Re le si si ile yi li osan ati li oru.

Meter: 8.7.8.7.8.7.

Scripture: I A. Oba 8:29

1

mfKristi n’ipile t’o daju.

Krist’ l’Ori at’lgunle

Asayan at’Iyebiye,

O so gbogbo Ijo lu;

Iranwo Sioni Mimo,

Igbekele Re titi.

2

mpSi tempili yi l’an pe O,

JO, wa loni, Oluwa;

Ni opo inu rere Re;

Gbo ebe eniyan Re;

Ma da ekun ibukun Re

Sinu ile yi titi.

3

Fun awon omo Re l’ebun

Ti won ba toro nihin

Ore ti won ba si ri gba

Ko ma je ti won titi;

Nikeyin, ninu ogo Re

Ki won ma ba O joba.

4

ffOgo at’ola fun Baba,

Ogo at’ola f’Omo,

Ogo at’ola fun Emi,

Metalokan titi lae.

At’ayeraye, Okanna.

Bakanna titi aye