Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 894

Ki oju Re le fi si ile yi li osan ati li oru.

Meter: L.M

Scripture: I A.Oba 8:29

1

mfAfi ipile yi lele

Ni oruko Re Oluwa

Awa mbe O Oluwa wa

Ma toju ibi mimo yi.

2

’Gba eniyan Re ba nwa O;

T’elese nwa O n’ile yi,

Gbo, Olorun lat’ orun wa

F’ese won ji won, Olorun.

3

Gba t’awon ’ranse Re nihin

Ba nwasu ’hinrere Kristi;

Sibe jeki ’se ’yanu nla

Ma se nipa oruko Re

4

f’Gb’ awon omode ba si nko

Hosana si Kristi Oba won

K’angeli ba won ko pelu,

K’orun at’aye jo gberin.

5

fJehofa O ha ba ni gbe

Ni aye buburu wa yi?

Jesu O ha je Oba Wa?

K’Emi Mimo si ma gbe hin?

6

fMa je ki ogo Re kuro

Ninu ile ti a nko yi;

Se ’joba Re ni okan wa,

Si te ite Re sinu wa.