Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 896

Ki O si gbo li orun, ibugbe Re, gbo, ki O si dariji.

Meter: 7.5.7.5.7.5.7.5.8.8.

Scripture: I A. Oba 8:30

1

mpGb’alareti nwa ’simi

Sa wa odo Re;

’Gba eni ti orun nwo

Gb’eru re le O;

’Gba eni nwa alafia

Ke pe oko Re;

’Gb’elese ti nwa iye

Wole l’ese Re;

crJo, Oluwa, gbo igbe won

fLati ibugbe Re l’orun.

2

mp’Gba eni ti aye su

Gb’okan re s’oke;

’Gbat’ asako ba pada

S’ife Baba re;

T’agberaga ba wole

Lati w’oju Re;

T’eni ebi kese re

Wa sib’ite Re

crJo, Oluwa, gbo igbe won

fLati ibugbe Re l’orun.

3

mp’Gbat’ alejo nwa ’bugbe

Ti y’o simi si;

Ti elebi nwa onje,

T’otosi nw’oro,

’Gbat’ atuko loju 'bu

Wo O fun ’ranwo;

T’eni nja l’oju ogun

Gb’okan re si O;

crJo, Oluwa gbo igbe won

fLati ibugbe Re l’orun.

4

mp’Gbati eni ti nsise

Li arin ilu,

T’O1us’agutan n’igbe

P’oko Olorun;

Gba t’awon alagbara,

T’adun aye su.

Ti nlepa ayo t’orun

Pe oko nla ni;

crJo, Oluwa, gbo igbe won

fLati ibugbe Re l’orun.

5

mp’Gbati ewe at’odo,

Ati arugbo

Ba nsaferi oju Re

Nipa adura;

’Gbat’ opo ba nke pe O

N’nu ’banuje re

Nigbati alail’obi

Ko osi re wa;

crJo, Oluwa, gbo igbe won

Lati ibugbe Re l’orun.

6

mp’Gba gbogb’eda nkerora

N’nu iponju won

Ti omo Re, asako,

Mi imi edun,

T’ijo Re, t’on t’omije

Ba nwa ibugbe,

Ti nfi edun ke wipe

Jesu, jare, wa;

crJo, Oluwa, gbo igbe won

fLati ibugbe Re lorun.