Hymn 897
Nitori Ogo Oluwa kun ile Oluwa.
Meter: 7.6.7.6.7.6.7.6.
Scripture: I A. Oba 8:11
mf’Wo Eni ti owo Re.
Mu wa d’ojo oni,
crJo tewo gba ope wa,
F’eti s’adura wa;
Ki imurasile wa
Fun isin oni je
Lati f’ara wa fun O
Pel’ okan isokan.
fA yin O fun ile yi
T’a ko li ase Re;
F’a won t’o se iranwo
Fun ise kiko re;
Je ki a ri ogo Re;
Ninu Tempili Re;
diNitor’ asan l’ewa re
Bi O ko si nibe.
mfNigbati a ba npejo
Lati josin nihin,
crJe k’ar’agbara oto
K’adura wa goke;
K’osise gb’okan s’oke
Si ohun ti orun,
Ki t’agba t’ewe l’okun;
Ki aye mo ’fe Re
mfB’odun ti nyi lu odun
Ti ife toto npo
Si ile mimo Re yi
Ti a si nranti re,
crKi ola at’ogo Re
Je eyi titi lae
Pe, opolopo t’ihin
Ri ona s’odo Re.
f’Ranwo awon Baba wa,
Ayo on ’reti wa;
Oluwa fun wa l’ebun
Opo ojo l’aye
’Wo mo edun okan wa,
A mbe niwaju Re
Jo, wa f’oju rere Re
Se ’le yi ni Tire.