Hymn 898
Oluwa Olorun teti sile si adura ti iranse re ngba loni.
Meter: L.M
Scripture: I A. Oba 8:28
1
mfPelu wa, Oluwa loni
B’a ti nya ’le yi si mimo,
Gbo adura iranse Re,
K’o si f’eti si igbe won.
2
Je k’a ri alafia nihin,
At’ife ati otito;
Da won t’a ni tara sile
K’okan won kun f’ore-pfe.
3
mpGbo mi edun awon tire
Ki alare ri isimi;
Gbo gbe onirobinuje
Si bukun fun okan gbogbo.
4
Fi itara kun okan wa,
Si je ki okan wa gbona
’Gbat’ a ngbo ’hinrere nihin;
T’a si nkede oruko Re.
5
mfSo Oku d’alaye nihin,
K’odi korin, k’aditi gbo,
Si fun awon onirele
N’ifiji at’alafia.
6
fSe ile yi n’ibugbe
K’a ma ri oju Re nihin;
K’eyi je ile Olorun
Ati enu bode orun.