Hymn 899
Nigbati afi ipile ile yi lele, awon pupo si ho iho nla fun ayo.
Meter: L.M.
Scripture: Esra 3:12
1
fOlorun, a yin ’toju Re
Lori agbala mimo yi;
Ota ko gbodo gbogun ti,
K’o daya fo olusin Re.
2
fA o mo ’giri yi f’ola Re,
K’o ma ho fun ’yin Re titi;
’Gbat’ o ba si sokale wa,
F’ore-ofe Re kunnu re.
3
mf’Gbat’ojo nla ni ba side,
T’Olorun y’o d’aye lejo,
crK’o han fun gbogbo aye pe
fOpo l’a bi s’ogo nihin.