Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 900

Nitoriti afi ipile re sole lori apata.

Meter: 6.5.6.5.D.

Scripture: Mat. 7:25

1

mfKristi ni ipile

Ile t’a nko yi;

K’odi re je ’gbala

K’ona re je ’yin

Ki iloro sowon

L’oju Oluwa;

K’okan awon ti nsin

Nihin je mimo.

2

mfNihin ni k’Emi Re

Ma gbp eje wa;

K’alaisan r’iwosan,

K’a m’asako bo;

K’onirobinuje

Ri ’dariji gba;

K’awon t’o ti pinya

Tun ni irepo.

3

mfJeki a ri eri

Pe, Ombe nihin;

K’awon t’a de l’ewon

D’ominira nihin;

crK’imole tan nihin

Si awon Tire.

Lati gbe wa soke

Si ohun t’orun.

4

fNihin ni k’a juba

Olorun Baba

Ati Kristi Omo

Pel’Emi mimo;

Titi gbogbo eda

Y’o wole fun O,

Ti won o ma yin O;

Oluwa aye.