Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 901

Solomoni si beresi iko ile Oluwa.

Meter: 12.9.12.9. & Ref.

Scripture: IIKro. 3:1

1

mfOyigiyigi, Oba Onise ’yanu

Atobiju Olodumare,

Abani-kedun, Oluranlowo alaini

Iwo l’ope ye, Olugbala

CHORUS

fDide, Olorun Solomoni, dide,

Ba wa ko ile yi pari,

Je k’a nipin lati josin nibe

Pelu orin ’yin on ope.

2

crIwo Olorun to bukun fun Jakobu,

Ran wa lowo lori ise yi

Ki ’lekun orun si, k’ojo bukun si ro

S’ori t’agba t’ewe Ijo wa

3

fEje ka fi iyin at ’ope f’Oluwa

Fun ore-ofe nla to fun wa

Lati ko ile mimo nigba aye wa

Fun ogo oruko Oluwa.

4

crEranti ileri t’Olugbala wa se

Lat’enu awon iranse Re

Pe, a ti fi isura nla pamo fun wa

Nibi kokoro ko le ba je.

5

IWO Olorun eleda ohun gbogbo

Je ka ni ipin n’nu ise yi,

mfFun wa n’irepo ati isokan emi.

Lati pari ‘le yi f’ogo Re

6

mfBi Baba ti f’owo ’tun Re gbe Jesu ga

Leyin t’ise igbala pari,

crFun wa ni ’segun, ko si gbe ijo yi ga,

K’O si so di ile irorun.