Hymn 903
Adura ki adura tabi ebe ki ebe ti a ba ti odo enikeni gba ki iwo ki o gbo, ki o si dahun.
Meter: L.M.
Scripture: II Kro. 6:29-30
1
mfNihin, l’oko Re Oluwa,
A ko ’le ’rupe yi fun O,
Yan fun ’bugbe Re pataki,
K’O si so lowo asise.
2
mpGb’eyan Re ba nwa O nihin,
T’elese mbebe fun iye,
Gbo lat’ibugbe Re Orun,
Gbat’O ba gbo, k’O dariji.
3
mfGbat’ojise Re ba nwasu
Ihinrere Jesu nihin,
Nip’agbara oko Re nla,
K’a ri ami on ’se ’yanu.
4
’Gba t’ohun ewe ban korin,
Hosana s’Oba won l’oke,
K’aye at’orun gberin na,
Ki angeli ko Hosana.
5
fK’ogo Re ma f’ihin ’le lae
Sibe, ma yan ’le yi nikan,
K’ijoba Re d’okan gbogbo,
T’ite Re si gbogbo aye.