Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 904

Nitori nibiti eni meji tabi meta ba ko ara won jo li oruko mi, nibe li emi o wa li arin won.

Meter: L.M.

Scripture: Mat. 18:20

1

mfOlorun Baba, Krist’Omo,

Ati Emi, Metalokan,

Gba ore ti a mu wa yi,

T’a fife onigbagbo se.

2

K’imole oro Re f’oye

F’agba ati ewe nihin,

Gbin ore ni s’okan pupo,

Ti gba ni la lowo ese

3

Nihin, ki Jesu f’ipa han,

Ti so okun di imole,

K’O si s’ilekun ’fe paya,

T’o yo si ibukun loke,

4

fJesu Oluwa, Alade,

’Wo t’awon mimo nwole fun,

Gba ore iyin t’a fun O,

K’O si f’ogo Re kun’le yi.