Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 905

Ibukun ni fun awon ti ngbe inu ile re:

Meter: 7.7.7.7.D

Scripture: OD. 84:4

1

fAlafia fun ’le yi,

At’awon ti ngbe ’nu re:

K’alafia Olorun

B’eni alafia gbe.

Jeki Emi sokale;

K’ibukun na ba le wa!

Om’alafia, gb’ade re,

Ekun-rere or’-ofe.

2

mfKristi, ’Wo l’Oluwa mi,

Je ki nje akede Re;

Ma s’ai ranti oro Re;

Be won wo, si be mi wo!

K’igbala wo ile yi,

F’awon ti ngbe inu re

Gba okan wa low’ese,

Fi wa se ibugbe Re.

3

mfMase jek’ a se are,

Tit’ileri na y’o se,

Titi ao fi je Tire

Nipa isodimimo;

crFun wan’ife akotun,

K’a le ri ’re t’o sonu,

K’a je tempil’Olorun,

Baba, Omo at’Emi.