Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 909

E ma duro sinsin laiyese. Ki e si mapo Si ni ise Oluwa nigbagbogbo

Meter: 7.6.7.6.d

Scripture: I Kor. 15:58

1

mfOluwa ‘kore emi

Ninu oko aye,

Nibi t’awon angeli,

Y’o ko iti won jo,

crGb’awon wonyi fun ‘se Re,

Fi ife s’okan won,

Je k’a ti owo won mu,

‘Joba Re yara de.

2

mfFi won se alagbase

L’ogba Re, Oluwa

Fun won ni itelorun

Lati sise fun O;

‘Gbat’ O ba pe won rele

diJe k’o te won lorun

Pe awon pin n’nu lala

Ti nmu ‘joba Re bo

3

mfMa wa pelu won, Baba

Ma ba won gbe Omo

Ma so won, Emi Mimo

Metalokan laelae

diFi won joye alufa

Lati f’oto sin O

Si fi ore re kun won

Loni ati laelae

4

mfWa, iwo Emi Mimo

Fi imole kun wa,

Fi ewu ailabawon

Wo wa ka fun alulau,

Pelu wa b’a ti duro

N’nu ile mimo Re;

Ya eeyan Re si mimo

Ni gbogbo ile yi