Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 91

Jesu Kristi, eleri Olooto, Akobi ninu awon oku.

Meter: 8.7.8.7.4.7.

Scripture: Ifi. 1:5.

1

fOluwa gunwa lori’te

mfAkobi awon t’o sun

On nikan l’Onigbeja wa

To ngbe wa leke ota

crAleluya, Aleluya

fJesu li Onje Iye.

2

mfAwa njuba, awa nsape;

fKabiyesi Oba wa,

mfBusi igbagbo wa loni

K’a le tubo mo O si,

fAleluya, Aleluya

Iwo njoba larin wa.

3

mpBi a ko tile le ri O

Bit’awon ti igbani,

crAwa at’awon Angeli

Nyin iru-omo Jese.

Aleluya, Aleluya,

TEWO gba ijosin wa.

4

Od’agutan t’a fi rubo

Ti s’etutu f’ese wa

Ko tun si ebo miran mo

Eje Re ti to fun wa.

Aleluya, Aleluya,

Eje na lo nwe wa mo.

5

O nfi onje iye bo wa

Manna didun lat’orun

K’orun at’aye korin na

Orin ’yin s’Od’agutan.

Aleluya, Aleluya,

O jinde, O si goke.