Hymn 915
Ki emi ki o le mo bi a ti i soro li akoko fun alare.
Meter: L.M.
Scripture: Isa. 50:4.
1
mfKo mi Oluwa, bi a ti
Je gbohungbohun oro Re;
B’o ti wa mi, je k’emi wa
Awon omo Re t’o ti nu.
2
To mi, Oluwa, ki nle to
Awon asako si ona;
Bo mi Oluwa, ki nle fi
Manna Re b’awon t’ebi npa
3
fFun mi l’agbara: fi ese
Mi mule lori apata;
diKi nle na owo igbala
S’awon t’o nri sinu ese
4
mfKo mi Oluwa, ki nle fi
Eko rere Re k’elomi;
F'iye f‘oro mi, k'o le fo
De ikoko gbogbo okan
5
fF’isimi didun Re fun mi,
Ki nle mo, bo ti ye lati
Fi pelepele s’oro Re
Fun awon ti are ti mu.
6
fFi ekun ore Re fun mi,
Titi okan mi y’o fi kun
Fun tara l’ero at’oro
Lati kede ’fe oun ’yin Re
7
Lo mi, Oluwa, a n’emi
Bi o ti fe, nigbakugba,
Titi em’o fi r’oju Re,
Ti un o pin ninu ogo Re