Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 918

Emi wa pelu yin ani titi de opin aye.

Meter: 8.7.8.7.8.7.

Scripture: Mat. 28:20.

1

mfSin awon onse Re, sin won

W’oba efufu igbi;

A de won, O da won sile,

Won nlo’da eru ni’de:

crWa pelu won, wa pelu won,

Apa Re, l’o le gbala.

2

Won f’ile at’ore sile

Ni ase Re Oluwa;

N’ile ati loju omi

Je Alafehinti won,

crJo pelu won, jo pelu won,

Si ma to won lailewu.

3

mp’Biti ’se won ko m’eso wa,

T’o dabi ’se won jasan;

Sunmo won l’anu Re, Jesu

Mu ireti won duro;

Ran won lowo, ran won lowo,

K’itara won tun soji.

4

mfN’nu opolopo isoro,

K’won gbekele O, Jesu

’Gbat’ ise na ba si ngbile,

Ki won mase gberaga;

crMa fi won ’le, ma fi won ’le

Titi won o r’oju Re

5

fNibiti won o fayo ka

Eso irugbin aye;

Nibiti won o wa titi

Lodo Olupamo won;

Pelu ’segun, pelu ’segun

Won o maa korin Jesu.