Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 919

Oluwa si mba won sise

Meter: 6.6.4.6.6.6.4.

Scripture: Mk. 16:20.

1

fOluwa wa mimo,

Ti ogun orun nyin,

Masai gbo wa:

Kerubu, Serafu,

At’ awon angeli,

S’odo Re ni won nmu

Iyin won wa.

2

mpFun oro Re n’ipa,

Bukun ’ranse Re yi;

Gba ise re;

Bi Jesu si ti nfi

Ami si Oro re,

Ran Emi Re mimo

Lati fi han.

3

mfB’odun ti nrekoja,

Ki ayo ma po si

Ju t’oni lo;

Yan kun ’nu ilena,

Ran ’ranse Re lowo,

K’aye gba oto Re

Oluwa wa.