Hymn 921
Ki enyin ki o be Oluwa Ikore, ki o le ran alagbase sinu ikore Re.
Meter: L.M.
Scripture: Lk. 10:2.
1
mpOlorun ’kore, te ’ti Re.
F’ara Re han l’ogun Sion;
Ran ojise t’o n’itara,
T’o yara lati gb’ase Re
2
mpWo wa l’oju Oluwa wa,
Ikore pon, o nre dede;
Ile nla si siwaju wa,
Ise po, osise kere.
3
mpFi owo agbara Re to
Omo Sion nibi gbogbo,
Bi alore ’gbala ofe,
Ki won bukun iran kiku.