Hymn 923
E ma ko won lati ma kiyesi ohun gbogbo.
Meter: S.M.
Scripture: Mat. 28:20.
1
Eyin ’ranse Kristi,
Gbo ohun ipe Re:
E tele Ona t’O fi han,
Eyi t’a pe yin si.
2
mfBaba ti eyin nsin,
Alagbara ni se;
E gbekele ileri Re,
E ja bi okunrin.
3
LO f’Olugbala han,
Ati anu nla Re.
F’awon otosi elese.
Ninu omo Adam’
4
fL’oruko Jesu wa,
A ki yin, Ona ‘re!
A mbe Eni t’Oran yin lo,
K’O BUSI ISE yin.