Hymn 924
Nitoripe Oluwa Olorun re, On ni O mba o lo.
Meter: 11.11.11.11 & Ref.
Scripture: Deut. 31:6.
1
mfJesu y’o pelu re l’ona re gbogbo,
Jesu y’o pelu re, y’o si maa to O
Larin asale ati l’ori oke,
Jesu y’o wa pelu re nigba gbogbo.
CHORUS
fJesu y’o pelu re, Jesu y’o pelu re,
Y’o je ore at’olutunu fun o;
Jesu y’o pelu re, Jesu y’o pelu re;
Jesu y’o pelu re de opin.
2
Jesu y’o pelu re l’ona re gbogbo
Jesu y’o pelu re, y’o si di o mu
mpLarin afonifoji ibanuje,
Jesu y’o pelu re, ma so ’reti nu.
3
Jesu y’o pelu re l’ona re gbogbo.
Jesu y’o pelu re, l’ona ajo re,
crLarin isan ’danwo s’ona ilu ni,
Jesu y’o pelu re, sa gbeke re l’E.