Hymn 926
Awon ti o nsise ninu omi nla won ri ife Oluwa, ati ise iyanu Re ninu ibu.
Meter: 8.8.8.D.
Scripture: OD. 107:23-24.
1
mfBaba wa Olodumare,
’Wo t’O kawo igbi omi,
’WO t’O ti f’ipo okun fun,
Ti ko le re ibe koja;
p,crGbo tiwa, ’gbat’a nkepe O
diF’awon t’o wa l’oju omi.
2
mfOlugbala ’Wo t’oro Re
Mu igbi omi pa roro,
IWO t’O rin l’ori omi,
T’O sun b’enipe ko si nkan
p,crGbo ti wa, ’gbat’ a nkepe O
diF’awon t’o wa l’oju omi.
3
mf’WO Emi Mimo, t’o rado
B’omi aye ni ’jo kini;
T’O mu ’binu re pa roro
Oluwa ’mole at’iye
p,crGbo tiwa, ’gbat’a nkepe O
diF’awon t’o wa l’oju omi.
4
fMetalokan, alagbara;
Dabobo won ninu ewu,
L’OWO apata at’iji,
L’OWO ina ati ota;
ffSi je k’a maa korin ’ yin Re
diL’or’ ile ati lor’ omi.