Hymn 931
Alafia mi ni mo fi fun yin.
Meter: S.M.
Scripture: Jn. 14:27.
1
mpA o pinya l’ara lo
S’oniruru ilu
mfSugbon awon ore Jesu
Wa n’isokan emi.
2
Jesu, Olori wa,
L’O da okan wa po,
Awa t’a mba rin ni mimo
L’O so d’okan l’emi.
3
crJek’a te siwaju
Ninu ise Jesu;
K’a ma tele Olusegun,
K’a bale segun si!
4
mfOgba Oluwa mbe
Niwaju On ’se Re;
Awa si nwo ere nla na,
Ti a nlo ba loke.
5
crK’ife at’ere wa
Goke nigbagbogbo.
Lati d’ebute’simi ni
Nibiti ’se wa pin.
6
Nibe n’ise wa tan,
Iya oun ’rora wa!
L’ebute ayeraye ni;
A ki yoo pinya mo.
7
Ilu alafia,
T’awon mimo pade!
mfNibe l’a or’oju ara wa,
T’a o yo mo ara wa.
8
T’awa-t’ijo ’saju
L’ao jumo gba ’bukun,
Ninu ayo l’ao tun wo
Isimi ailopin.