Hymn 932
Ki Oluwa alafia tikarare, ma fun yin ni alafia nigbagbogbo.
Meter: 6.6.8.4.
Scripture: II Tes. 3:16.
1
mpOro alafia
L’a fi sin yin, ara,
crK’ alafia bi odo nla
Ma ba yin lo.
2
mpN’nu oro adura,
A fawon ara wa
Le iso Oluwa lowo;
Ore tooto.
3
mfOro ife didun
L’a fi p’odigbose,
Ife wa ati t’Olorun
Y’o ba won gbe.
4
fOro ’gbagbo lile,
Ni igbekele wa
Pe, Oluwa y’o se ’ranwo
Nigba gbogbo.
5
Oro ’reti didun
Y’o mu ’pinya wa dun,
Y’o SO ayo t’o le dun ju
Ayo t’aye.
6
mfO digbose ara;
N’ife ati ’gbagbo
pTit’ao fi tun pade l’oke
N’ile l’orun.