Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 933

O mu won wa si ebute ife won.

Meter: c.m.

Scripture: OD. 107:30.

1

mfOlorun wa n’nu oko

Larin omi jinjin,

S’OLUSO wa ba ti nwa lo,

Ninu ajin oru.

2

Eru ko ye ki o ba wa,

Larin iji ti nja,

Niwon gba t’ O wa nitosi

Larin omi ti nru.

3

Iparoro ati Iji,

T’o nkoja lori ’le

IWO ni o da gbogbo won,

Won wa nikuwo Re.

4

Nigbat' awon Apositeli,

Wa lori ’gbi okun,

Ase kan lat’odo Re wa,

Mu dake roro wa.

5

mpGbati iji to buruju,

Banru l’atokan wa,

Oluwa ma sai ba wa gbo

F’alafia ba wa gbe.

6

mfNinu wahala aye yi,

Ma se amona wa,

Titi a o fide’le rere,

Nibi t’ese ko si.