Hymn 94
Li ori Re re li ade pupo wa.
Meter: D.S.M.
Scripture: Ifi. 19:12.
fE de l’ade pupo
Od’agutan Baba;
Gbo bi orin orun ti bo
Orin gbogbo mole:
Ji, okan mi korin
T’Eni to ku fun O,
Se l’Oba re togajulo
Titi ati laelae.
fS’Omo Wundia l’Qba!
Om’Olorun t’a bi
Ti ade Re n mi legbe fun
Ami isegun R?;
Silo ti a so tele,
Eka igi Jese,
Olus’agutan agbo Re
Omo ti Betlehem'.
fS’Oluwa ye l’Oba
To segun iboji
To si ji dide ni ‘SEGUN
F’awon to wa ‘gbala
Orin ogo la nko yi
T’Eni to ku, to ji
O ku ko ba mu iye wa
O ye ki ‘ku le ku
fSe l'Oba alafia!
‘Joba Re k’ yo lopin;
Nibiti ogun wole fun
Ife titi iyin
Ati yika ese
Re ti a kan niso
Egberun ede ni ’dapo
Yo korin didun si.
fOluwa loba
Ti O gunwa loke
Se l’Oba ti a fun l’oko
lyanu ’ti Ife;
E de l’ade pupo,
Awon ti ngbe aye
Ati gbogbo oba aye.
N’ tor’On l’Oba eda.
fSe l’Oba gbogbo’gba,
Qba ayeraye,
Eleda gbogbo irawo,
Agba ’yanu leyi:
Olurapada wa!
To ku nitori mi;
Iyin Re ki yo lopin
lae Laelae ati laelae.