Hymn 940
Ibukun ni fun oku ti o ku nipa ti Oluwa.
Meter: 6.6.6.6
Scripture: Ifi. 14:13.
1
pIbukun ni f’oku
T’o simi le Jesu
Awon t’o gb’ori won
Le okan aya Re
2
mfIran ’bukun l’eyi
Ko si b’oju l’arin,
Won ri Eni ’mole
Ti won ti fe l’airi.
3
Won bo lowo aye
Pelu aniyan re;
Won bo lowo ewu
T’o rin l’osan, l’oru.
4
mpOluso-Agutan
Nibit’ iji ki ja,
Mu won lo si papa
L’eba omi iye.
5
Lor’ iboji won
L’awa nsokun loni
Won j’en ’ire fun wa
T’a ki y’o gbagbe lae.
6
mpA k’y’o gb’ohun won mo;
Ohun ife didun
Lat’ oni lo, aye
Ki o tun mo won mo
7
crEyin oninure,
E fi wa sile lo
fA o sokun yin titi
ffJesu pa sokun ri.
8
Sugbon a fe gb'ohub
Olodumare na;
Y’o ko, y’o si wipe,
"E jinde, e si yo”