Hymn 942
Adorin odun, ni iye ojo odun wa.
Meter: L.M
Scripture: OD. 90:10
1
mfOlorun lat’ irandiran,
’Wo n’isimi at’abo wa,
K’a to da orun at’aye.
Giga ni ife Re l’oke.
2
mfO ti njoba k’igba to wa,
Tabi k’a to da eniyan;
Ijoba Re y’o wa laelae,
’Gbat’ igba at’aye ba pin.
3
mfIku, bi odo, ngba wa lo,
Aye wa bi itan lasan,
O dab’itanna owuro,
Ti a ke lu ’le, t’o si ro.
4
mfJek’a mo ailera eda
K’O sun ojo wa siwaju
pTit’ ao fi mura de iku,
Nipa ’wenumo or’-ofe