Hymn 95
Nitori ninu Re li a ti da ohun gbogbo, ohun ti mbe li orun ati ohun ti mbe li aye
Meter: 14.14.4.7.8.
Scripture: Kol. 1:16.
1
fYin Oluwa Olodumare,
Oba Eleda
Yin Okan mi to r’On ni ’lera
ati ’gbala re
Arakunrin,
Arabinrin sunmo ’hin
F’ayo at’orin juba Re
2
fYin Oluwa, Eni t’Ojoba
lor’ ohun gbogbo
To dabobo, to si gbe o ro
labe iye Re
O ha ri pe?
Gbogb’ ohun toto lo se
B’O ti lana n’ipase.
3
fYin Oluwa to mbukun ’se re
to si ngbeja re;
L’otito ire ati anu Re nto o leyin
’Gbana ronu
Ohun t’Oluwa le se
Eni to fe o, t’O yan o.
4
fYin Oluwa! Ki gbogb’ eya
ara mi juba Re
Ki gbogbo ohun t’o l’emi
wa pelu iyin Re.
Je ki iro
Amin dun jake jado,
Layo lao juba Re titi.