Hymn 950
Ohun ogo li a nso ni tire, ilu Olorun.
Meter: 8.7.8.7.D.
Scripture: OD. 87:3
1
fOhun ogo Re l’a nroyin,
Sion, ti Olorun wa;
Oro Eni t’a ’ko le ye,
Se o ye fun ’bugbe Re
’Pile re mbe lor’Apata,
Kini, le mi ’simi re?
A f’odi ’gbala yi o ka
K’o le ma rin ota re;
2
Wo! omi ’ye ti nsan lati
Isun ijinle ’fe wa,
O to fun gbogbo omo re
Eru aini ko si mo;
Tal’ o le re, ’gba odo na
Ba nsan, t’o le pongbe re?
Or’-ofe Olodumare
Ki ye lat’ irandiran.
3
crOlugbala, b’O ba ka mi
Kun awon ara Sion
B’aye nkegan, t’o si nsata,
Un'o f’itiju na s’ogo;
pSisa l’ohun afe aye,
Pelu ogo asan re,
fIsura toto at’ayo,
Kik’omo Sion l’o mo