Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 951

Ninu ile baba mi, opolopo ibugbe lo wa.

Meter: 7.5.6.6.7.7.7.7.

Scripture: Jn. 14:2

1

fIle ailopin kan wa,

T’o ndan, t’o dara;

Nib’ayo pipe wa,

Ko si oru nibe,

Awon Angeli si nkorin

Nigbagbogbo yi ’te ka;

crNigbawo ni un o ri o

Ile didan, didan yi?

CHORUS

ffIle didan yi,

Ile mimo yi,

Ile igbala wa,

Ibugbe ogo!

2

mfItanna didun wa n’be,

N’ile didan yi;

Awon omode nko

Orin iyin Jesu;

fA! b’orin na ti dun to;

Won y’ite funfun na ka;

Nigbawo ni un o ri o,

Ile didan, didan yi?

3

crLaipe ngo dapo mo won

Ni oke orun;

mfKristi ni ’gbala mi

Ese ti un o beru?

fLaipe oju mi y’o ri

B’o ti joko lor’ite;

’Gbana emi o ri O

Ile didan, didan yi.