Hymn 958
Eni ti o ba segun ni yio jogun nkan wonyi.
Meter: 11.11.11.11.
Scripture: Ifi. 21:7
1
Ile ewa wonni, b’o ti dara to!
Ibugbe Olorun, t’oju ko ti ri;
Tal’ o fe de ibe, leyin aye yi?
Tal’ o fe k’a wo on ni aso funfun?
2
pAwon wonni t’o ji ninu orun won,
Awon t’o ni ’gbagbo si nkan t’a ko ri:
Awon t’o k’aniyan won l’Olugbala,
Awon ti ko tiju agbelebu Krist’.
3
crAwon ti ko nani gbogbo nkan aye,
Awon t’o le soto de oju iku.
Awon t’o nrubo ife l’ojojumo,
Awon t’a f’igbala Jesu rapada.
4
fItiju ni fun yin, Om’ogun Jesu,
Eyin ara ilu ibugbe orun,
Kinla! e nfi fere at’ilu sire
’Gbat’ o ni k’e sise, t’o si pe, “E ja!”
5
crB’igbi omi aye si ti nkolu wa,
Jesu, Oba Ogo, si si wa l’eti;
Adun t’o wa l’orun ilu mimo ni,
Nibit’ isimi wa, lae ati laelae.