Hymn 959
Ninu ile Baba mi opolopo ibugbe lo wa.
Meter: 6.6.6.D.
Scripture: Jn. 14:2
1
mfIle ’bukun kan wa,
Leyin aye wa yi,
Wahala, irora,
At’ekun ki de ’be
crIgbagbo y’o d’opin,
Ao de’reti l’ade,
fImole ailopin
Ni gbogbo ibe je
2
mfIle kan si tun mbe
Ile alafia
crAwon Angeli rere
Nkorin n’nu re laelae;
ffYi’te ogo Re ka
L’awon egbe mimo
Nwole, won nteriba
F’eni Metalokan.
3
mfAyo won ti po to;
pAwon t’o ri Jesu,
crNibit’o gbe gunwa,
T’a si nfi ogo fun,
fWon nkorin iyin Re;
Ati t’isegun Re;
Won ko dekun royin
Ohun nla t’o ti se.
4
mfW’oke, eyin mimo,
E le iberu lo,
pOna hiha kan na
L’Olugbala ti gba;
crE fi suru duro
Fun igba die sa;
fT’erin-t’erin l’On o
Fi gba yin s’odo Re