Hymn 964
A wa si nlo si ibiti Oluwa wipe emi o fi fun yin Iwo ba wa kalo.
Meter: 6.4.6.4.6.7.6.4.
Scripture: Num. 10:29
1
mfIle ayo kan wa
Ti o jina;
Ni b’awon mimo wa,
Won nran b’orun;
A! won nkorin didun
Yiye l’Olugbala wa
Ki iyin Re ko ro,
Yin, yin laelae.
2
mfWa sile ayo yi,
Wa, wa k’a lo,
E se nsiyemeji?
E se nduro?
Ao wa l’Alafia
Kuro l’ese at’aro,
A o ba O joba,
L’ayo laelae.
3
fOju gbogbo won ndan
N’ile ayo,
N’ipamo Baba wa,
Ife ki ku.
Nje sure lo s’ogo
Gba ade at’ijoba
T’o mo ju orun lo,
Joba titi.