Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 965

Beli awa o si wa lae lodo Oluwa

Meter: D.S.M.

Scripture: I Tes. 4:17

1

mf“Lae lodo Oluwa,”

Amin, beni kori,

crIye wa ninu oro na,

Aiku ni titi lae

mpNihin ninu ara

Mo s’ako jina s’l

crSibe alale ni mo nfi

Ojo kan sunmo ’le.

2

mfIle Baba l’oke

Ile okan mi ni:

Emi nfi oju igbagbo

Wo ’bode wura re!

pOkan mi nfa pupo

S’ile na ti mo fe

crIle didan, t’awon mimo,

Jerusalemu t’orun.

3

diAwosanma dide,

Gbogbo ero mi pin;

Bi adaba Noa, mo nfo

Larin iji lile

crSugbon sanma kuro,

Iji si rekoja

Ayo ati alafia

Si gba okan mi kan.

4

mfL'oro ati l’ale,

L’osan ati l’oru

Mo ngbo orin orun bori

Rudurudu aye;

ffOro ajinde ni,

Hiho isegun ni;

Lekan si, lae l’od’Oluwa,

crAmin, beni k’o ri.